-
Jóòbù 2:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Lẹ́yìn náà, nígbà tó di ọjọ́ tí àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́*+ ń wọlé láti dúró níwájú Jèhófà,+ Sátánì náà wọlé sáàárín wọn kó lè dúró níwájú Jèhófà.+
2 Jèhófà bi Sátánì pé: “Ibo lo ti ń bọ̀?” Sátánì dá Jèhófà lóhùn pé: “Látinú ayé, mo lọ káàkiri, mo sì rìn káàkiri nínú rẹ̀.”+ 3 Jèhófà sì bi Sátánì pé: “Ṣé o ti kíyè sí* Jóòbù ìránṣẹ́ mi? Kò sí ẹni tó dà bíi rẹ̀ ní ayé. Olódodo àti olóòótọ́* èèyàn+ ni, ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì kórìíra ohun tó burú. Kò fi ìwà títọ́ rẹ̀ sílẹ̀ rárá,+ bó tiẹ̀ jẹ́ pé o fẹ́ sún mi+ láti pa á run* láìnídìí.”
-