-
Jóòbù 1:6-8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Ó wá di ọjọ́ tí àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́*+ ń wọlé láti dúró níwájú Jèhófà,+ Sátánì+ náà sì wọlé sáàárín wọn.+
7 Jèhófà bi Sátánì pé: “Ibo lo ti ń bọ̀?” Sátánì dá Jèhófà lóhùn pé: “Látinú ayé, mo lọ káàkiri, mo sì rìn káàkiri nínú rẹ̀.”+ 8 Jèhófà sì bi Sátánì pé: “Ṣé o ti kíyè sí* Jóòbù ìránṣẹ́ mi? Kò sí ẹni tó dà bíi rẹ̀ ní ayé. Olódodo àti olóòótọ́* èèyàn+ ni, ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì kórìíra ohun tó burú.”
-