-
2 Sámúẹ́lì 16:5-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Nígbà tí Ọba Dáfídì dé Báhúrímù, ọkùnrin ará ilé Sọ́ọ̀lù kan tó ń jẹ́ Ṣíméì+ ọmọ Gérà jáde wá, ó sì ń ṣépè bí ó ṣe ń bọ̀.+ 6 Ó ń sọ òkúta lu Dáfídì àti gbogbo ìránṣẹ́ Ọba Dáfídì àti gbogbo àwọn èèyàn náà títí kan àwọn alágbára ọkùnrin tó wà lápá ọ̀tún àti lápá òsì rẹ̀. 7 Bí Ṣíméì ṣe ń ṣépè ló ń sọ pé: “Kúrò níbí, kúrò níbí, ìwọ apààyàn aláìníláárí yìí!
-