11 Ilẹ̀ tó ní àwọn òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ ni ilẹ̀ tí ẹ fẹ́ sọdá lọ gbà.+ Òjò tó ń rọ̀ láti ọ̀run ló ń bomi rin ín;+12 Jèhófà Ọlọ́run yín ló ń bójú tó ilẹ̀ náà. Ojú Jèhófà Ọlọ́run yín kì í sì í kúrò ní ilẹ̀ náà, láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún títí di ìparí ọdún.
17 bó tilẹ̀ jẹ́ pé, kò ṣàìfi ẹ̀rí irú ẹni tí òun jẹ́ hàn+ ní ti pé ó ń ṣe rere, ó ń rọ òjò fún yín láti ọ̀run, ó sì ń fún yín ní àwọn àsìkò tí irè oko ń jáde,+ ó ń fi oúnjẹ bọ́ yín, ó sì ń fi ayọ̀ kún ọkàn yín.”+