-
Jóṣúà 3:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Gbàrà tí àwọn tó gbé Àpótí náà dé Jọ́dánì, tí àwọn àlùfáà tó gbé Àpótí náà sì ki ẹsẹ̀ wọn bọ etí omi náà (ó ṣẹlẹ̀ pé odò Jọ́dánì máa ń kún bo bèbè rẹ̀+ ní gbogbo ọjọ́ ìkórè), 16 omi tó ń ṣàn wá látòkè dáwọ́ dúró. Ó dúró bí ìsédò* síbi tó jìnnà gan-an ní Ádámù, ìlú tó wà nítòsí Sárétánì, èyí tó sì lọ sí Òkun Árábà, Òkun Iyọ̀,* ṣàn lọ títí tó fi gbẹ. Omi odò náà dáwọ́ dúró, àwọn èèyàn náà sì sọdá síbi tó dojú kọ Jẹ́ríkò.
-