ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 22:22-24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 “Ẹ ò gbọ́dọ̀ fìyà jẹ opó tàbí ọmọ aláìníbaba* kankan.+ 23 Tí ẹ bá fìyà jẹ ẹ́ pẹ́nrẹ́n, tó sì ké pè mí, ó dájú pé màá gbọ́ igbe rẹ̀;+ 24 màá bínú gidigidi, màá sì fi idà pa yín, àwọn ìyàwó yín yóò di opó, àwọn ọmọ yín yóò sì di aláìníbaba.

  • Diutarónómì 10:17, 18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Torí Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ Ọlọ́run àwọn ọlọ́run+ àti Olúwa àwọn olúwa, Ọlọ́run tó tóbi, tó lágbára, tó sì yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù, tí kì í ṣe ojúsàájú sí ẹnikẹ́ni,+ tí kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. 18 Ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo fún ọmọ aláìníbaba* àti opó,+ ó sì nífẹ̀ẹ́ àjèjì,+ ó ń fún un ní oúnjẹ àti aṣọ.

  • Sáàmù 10:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Àmọ́, o rí ìjàngbọ̀n àti ìdààmú.

      Ò ń wò ó, o sì gbé ìgbésẹ̀.+

      Ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn tó rin àrìnfẹsẹ̀sí yíjú sí;+

      Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ ọmọ aláìníbaba.*+

  • Sáàmù 146:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Jèhófà ń dáàbò bo àwọn àjèjì;

      Ó ń fún ọmọ aláìníbaba àti opó lókun,+

      Àmọ́, ó ń sọ èrò àwọn ẹni burúkú dòfo.*+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́