Sáàmù 22:11 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 11 Má jìnnà sí mi, torí wàhálà ti dé tán+Mi ò sì ní olùrànlọ́wọ́+ míì. Sáàmù 35:22 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 22 O ti rí èyí ná, Jèhófà. Má ṣe dákẹ́.+ Jèhófà, má jìnnà sí mi.+ Sáàmù 38:21, 22 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 21 Má fi mí sílẹ̀, Jèhófà. Má jìnnà sí mi,+ Ọlọ́run mi. 22 Tètè wá ràn mí lọ́wọ́,Jèhófà, ìgbàlà mi.+