11 “Wò ó, ọmọ mi, kí Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ, kí o ṣe àṣeyọrí, kí o sì kọ́ ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípa rẹ.+ 12 Kìkì pé kí Jèhófà fún ọ ní làákàyè àti òye+ nígbà tó bá fún ọ ní àṣẹ lórí Ísírẹ́lì, kí o lè máa pa òfin Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́.+