15 Nígbà yẹn àti ní àkókò yẹn, màá mú kí èéhù* òdodo kan hù jáde fún Dáfídì,+ á sì ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ àti òdodo ní ilẹ̀ náà.+16 Ní àkókò yẹn, a ó gba Júdà là,+ Jerúsálẹ́mù á sì máa wà ní ààbò.+ Ohun tí a ó sì máa pè é ni: Jèhófà Ni Òdodo Wa.’”+
8 “‘Àlùfáà Àgbà Jóṣúà, jọ̀ọ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ìwọ àti àwọn tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ tí wọ́n jókòó níwájú rẹ, torí àwọn ọkùnrin yìí jẹ́ àmì; wò ó! mò ń mú ìránṣẹ́ mi+ tó ń jẹ́ Èéhù+ bọ̀!