Àìsáyà 11:1 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 11 Ẹ̀ka igi+ kan máa yọ látinú kùkùté Jésè,+Èéhù+ kan látinú gbòǹgbò rẹ̀ sì máa so èso. Àìsáyà 11:4 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 4 Ó máa dá ẹjọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀ bó ṣe tọ́,*Ó sì máa fi òtítọ́ báni wí torí àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ tó wà ní ayé. Ó máa fi ọ̀pá ẹnu rẹ̀ lu ayé,+Ó sì máa fi èémí* ètè rẹ̀ pa ẹni burúkú.+ Jeremáyà 23:5 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 5 “Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “tí màá gbé èéhù* kan tó jẹ́ olódodo dìde fún Dáfídì.+ Ọba kan máa jẹ,+ á sì fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà, á dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, á sì ṣe òdodo ní ilẹ̀ náà.+ Hébérù 1:9 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 9 O nífẹ̀ẹ́ òdodo, o sì kórìíra ìwà tí kò bófin mu. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ, fi fòróró ayọ̀ yàn ọ́+ ju àwọn ojúgbà rẹ.”+
4 Ó máa dá ẹjọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀ bó ṣe tọ́,*Ó sì máa fi òtítọ́ báni wí torí àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ tó wà ní ayé. Ó máa fi ọ̀pá ẹnu rẹ̀ lu ayé,+Ó sì máa fi èémí* ètè rẹ̀ pa ẹni burúkú.+
5 “Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “tí màá gbé èéhù* kan tó jẹ́ olódodo dìde fún Dáfídì.+ Ọba kan máa jẹ,+ á sì fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà, á dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, á sì ṣe òdodo ní ilẹ̀ náà.+
9 O nífẹ̀ẹ́ òdodo, o sì kórìíra ìwà tí kò bófin mu. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ, fi fòróró ayọ̀ yàn ọ́+ ju àwọn ojúgbà rẹ.”+