5 “Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “tí màá gbé èéhù* kan tó jẹ́ olódodo dìde fún Dáfídì.+ Ọba kan máa jẹ,+ á sì fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà, á dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, á sì ṣe òdodo ní ilẹ̀ náà.+
8 “‘Àlùfáà Àgbà Jóṣúà, jọ̀ọ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ìwọ àti àwọn tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ tí wọ́n jókòó níwájú rẹ, torí àwọn ọkùnrin yìí jẹ́ àmì; wò ó! mò ń mú ìránṣẹ́ mi+ tó ń jẹ́ Èéhù+ bọ̀!