-
Diutarónómì 29:19, 20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 “Àmọ́ tí ẹnì kan bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ìbúra yìí, tó sì ń fọ́nnu lọ́kàn ara rẹ̀ pé, ‘Tí mo bá tiẹ̀ fi àáké kọ́rí, tí mò ń ṣe ohun tí ọkàn mi fẹ́, màá ní àlàáfíà,’ gbogbo ohun* tó wà lọ́nà rẹ̀ ló máa pa run, 20 Jèhófà ò ní ṣe tán láti dárí jì í.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa bínú gidigidi sí ẹni náà, ó dájú pé gbogbo ègún tí wọ́n sì kọ sínú ìwé yìí máa wá sórí rẹ̀,+ ó sì dájú pé Jèhófà máa pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run.
-