33 Ọlọ́run ti mú un ṣẹ pátápátá fún àwa ọmọ wọn bó ṣe jí Jésù dìde;+ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú sáàmù kejì pé: ‘Ìwọ ni ọmọ mi, òní ni mo di bàbá rẹ.’+
5 Bí àpẹẹrẹ, èwo nínú àwọn áńgẹ́lì ni Ọlọ́run sọ fún rí pé: “Ìwọ ni ọmọ mi; òní ni mo di bàbá rẹ”?+ Tó sì tún sọ fún pé: “Màá di bàbá rẹ̀, á sì di ọmọ mi”?+