-
Dáníẹ́lì 6:26, 27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Mo pàṣẹ pé ní gbogbo ibi tí mo ti ń ṣàkóso, kí àwọn èèyàn máa bẹ̀rù Ọlọ́run Dáníẹ́lì gidigidi.+ Torí òun ni Ọlọ́run alààyè, ó sì máa wà títí láé. Ìjọba rẹ̀ ò ní pa run láé, àkóso* rẹ̀ sì máa wà títí ayérayé.+ 27 Ó ń gbani sílẹ̀,+ ó ń gbani là, ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ní ọ̀run àti ní ayé,+ torí ó gba Dáníẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́* àwọn kìnnìún.”
-