21 Ni Mósè bá na ọwọ́ rẹ̀ sórí òkun;+ Jèhófà sì mú kí atẹ́gùn líle fẹ́ wá láti ìlà oòrùn ní gbogbo òru yẹn, ó sì bi òkun náà sẹ́yìn. Ó mú kí ìsàlẹ̀ òkun di ilẹ̀ gbígbẹ,+ omi náà sì pínyà.+
16 omi tó ń ṣàn wá látòkè dáwọ́ dúró. Ó dúró bí ìsédò* síbi tó jìnnà gan-an ní Ádámù, ìlú tó wà nítòsí Sárétánì, èyí tó sì lọ sí Òkun Árábà, Òkun Iyọ̀,* ṣàn lọ títí tó fi gbẹ. Omi odò náà dáwọ́ dúró, àwọn èèyàn náà sì sọdá síbi tó dojú kọ Jẹ́ríkò.