-
2 Kíróníkà 13:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 “Ní báyìí, ẹ rò pé ẹ lè dojú kọ ìjọba Jèhófà tó wà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Dáfídì, torí pé ẹ pọ̀ jù wọ́n lọ, ẹ sì ní àwọn ère ọmọ màlúù wúrà tí Jèróbóámù fi ṣe àwọn ọlọ́run fún yín.+ 9 Ṣebí ẹ ti lé àwọn àlùfáà Jèhófà jáde,+ ìyẹn àwọn àtọmọdọ́mọ Áárónì àti àwọn ọmọ Léfì, tí ẹ sì yan àwọn àlùfáà tiyín bí àwọn èèyàn ilẹ̀ míì ti ń ṣe?+ Ẹni tó bá mú akọ ọmọ màlúù kan àti àgbò méje wá* lè di àlùfáà àwọn ohun tí kì í ṣe ọlọ́run.
-