-
Nọ́ńbà 11:31-34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
31 Jèhófà wá mú kí afẹ́fẹ́ kan fẹ́ wá lójijì, ó gbá àwọn ẹyẹ àparò wá láti òkun, ó sì mú kí wọ́n já bọ́ yí ibùdó+ náà ká, nǹkan bí ìrìn àjò ọjọ́ kan lápá ibí àti ìrìn àjò ọjọ́ kan lápá ọ̀hún, yí ibùdó náà ká, ìpele wọn sì ga tó nǹkan bí ìgbọ̀nwọ́* méjì sílẹ̀. 32 Tọ̀sántòru ọjọ́ yẹn àti gbogbo ọjọ́ kejì ni àwọn èèyàn náà ò fi sùn, tí wọ́n ń kó àparò. Kò sẹ́ni tó kó iye tó dín sí òṣùwọ̀n hómérì* mẹ́wàá, wọ́n sì ń sá a yí ibùdó náà ká. 33 Àmọ́ nígbà tí ẹran náà ṣì wà láàárín eyín wọn, kí wọ́n tó jẹ ẹ́ lẹ́nu, Jèhófà bínú sí àwọn èèyàn náà gidigidi, Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa àwọn èèyàn náà lọ rẹpẹtẹ.+
34 Wọ́n wá pe ibẹ̀ ní Kiburoti-hátááfà,*+ torí ibẹ̀ ni wọ́n sin àwọn èèyàn tó hùwà wọ̀bìà torí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn+ wọn sí.
-