-
Ẹ́kísódù 17:6, 7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Wò ó! Èmi yóò dúró níwájú rẹ lórí àpáta tó wà ní Hórébù. Kí o lu àpáta náà, omi yóò jáde látinú rẹ̀, àwọn èèyàn náà á sì mu ún.”+ Mósè ṣe bẹ́ẹ̀ níṣojú àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì. 7 Ó wá pe ibẹ̀ ní Másà*+ àti Mẹ́ríbà,*+ torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá a jà àti pé wọ́n dán Jèhófà wò,+ wọ́n ní: “Ṣé Jèhófà wà láàárín wa àbí kò sí?”
-