ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 20:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 “Mú ọ̀pá, kí ìwọ àti Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ sì pe àwọn èèyàn náà jọ, kí ẹ sì bá àpáta sọ̀rọ̀ níṣojú wọn kí omi lè jáde nínú rẹ̀, kí o fún wọn ní omi látinú àpáta náà, kí o sì fún àpéjọ náà àti ẹran ọ̀sìn wọn ní ohun tí wọ́n máa mu.”+

  • Diutarónómì 8:14, 15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 má ṣe gbéra ga nínú ọkàn rẹ,+ kó sì mú kí o gbàgbé Jèhófà Ọlọ́run rẹ tó mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò ní ilé ẹrú,+ 15 ẹni tó mú ọ rin inú aginjù tí ó tóbi tó sì ń bani lẹ́rù,+ tó ní àwọn ejò olóró àti àwọn àkekèé, tí ilẹ̀ ibẹ̀ gbẹ tí kò sì lómi. Ó mú kí omi ṣàn jáde látinú akọ àpáta,+

  • Nehemáyà 9:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 O fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run nígbà tí ebi ń pa wọ́n,+ o fún wọn ní omi látinú àpáta nígbà tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n,+ o sì ní kí wọ́n wọ ilẹ̀ tí o búra* pé wàá fún wọn, kí wọ́n sì gbà á.

  • Sáàmù 78:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Ó la àpáta ní aginjù,

      Ó jẹ́ kí wọ́n mu àmutẹ́rùn bíi pé látinú ibú omi.+

  • Sáàmù 105:41
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 41 Ó ṣí àpáta, omi sì ṣàn jáde;+

      Ó ṣàn gba aṣálẹ̀ kọjá bí odò.+

  • 1 Kọ́ríńtì 10:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Ní báyìí, ẹ̀yin ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé gbogbo àwọn baba ńlá wa wà lábẹ́ ìkùukùu,*+ gbogbo wọn gba inú òkun kọjá,+

  • 1 Kọ́ríńtì 10:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 gbogbo wọn sì mu ohun mímu tẹ̀mí+ kan náà. Torí wọ́n ti máa ń mu látinú àpáta tẹ̀mí tó ń tẹ̀ lé wọn, àpáta náà sì dúró fún* Kristi.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́