-
Ẹ́kísódù 17:5, 6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Máa lọ níwájú àwọn èèyàn náà, kí o sì mú lára àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì dání pẹ̀lú ọ̀pá rẹ tí o fi lu odò Náílì.+ Mú un dání kí o sì máa lọ. 6 Wò ó! Èmi yóò dúró níwájú rẹ lórí àpáta tó wà ní Hórébù. Kí o lu àpáta náà, omi yóò jáde látinú rẹ̀, àwọn èèyàn náà á sì mu ún.”+ Mósè ṣe bẹ́ẹ̀ níṣojú àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì.
-
-
Sáàmù 78:15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Ó la àpáta ní aginjù,
Ó jẹ́ kí wọ́n mu àmutẹ́rùn bíi pé látinú ibú omi.+
-