14 má ṣe gbéra ga nínú ọkàn rẹ,+ kó sì mú kí o gbàgbé Jèhófà Ọlọ́run rẹ tó mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò ní ilé ẹrú,+ 15 ẹni tó mú ọ rin inú aginjù tí ó tóbi tó sì ń bani lẹ́rù,+ tó ní àwọn ejò olóró àti àwọn àkekèé, tí ilẹ̀ ibẹ̀ gbẹ tí kò sì lómi. Ó mú kí omi ṣàn jáde látinú akọ àpáta,+