6 Wò ó! Èmi yóò dúró níwájú rẹ lórí àpáta tó wà ní Hórébù. Kí o lu àpáta náà, omi yóò jáde látinú rẹ̀, àwọn èèyàn náà á sì mu ún.”+ Mósè ṣe bẹ́ẹ̀ níṣojú àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì.
11 Ni Mósè bá gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì fi ọ̀pá rẹ̀ lu àpáta náà lẹ́ẹ̀mejì, omi púpọ̀ wá ń tú jáde, àpéjọ náà àtàwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í mu ún.+