32Ní gbogbo àkókò yẹn, àwọn èèyàn náà rí i pé Mósè ń pẹ́ lórí òkè náà.+ Àwọn èèyàn náà wá yí Áárónì ká, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ó yá, ṣe ọlọ́run kan fún wa tó máa ṣáájú wa,+ torí a ò mọ ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí Mósè yìí, ẹni tó kó wa kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.”