29 Ó ń fún ẹni tó ti rẹ̀ ní agbára,
Ó sì ń fún àwọn tí kò lókun ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ okun.+
30 Ó máa rẹ àwọn ọmọdékùnrin, okun wọn sì máa tán,
Àwọn ọ̀dọ́kùnrin máa kọsẹ̀, wọ́n á sì ṣubú,
31 Àmọ́ àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà máa jèrè okun pa dà.
Wọ́n máa fi ìyẹ́ fò lọ sókè réré bí ẹyẹ idì.+
Wọ́n máa sáré, okun ò ní tán nínú wọn;
Wọ́n máa rìn, kò sì ní rẹ̀ wọ́n.”+