Léfítíkù 26:4 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 4 èmi yóò rọ ọ̀wààrà òjò fún yín ní àkókò tó yẹ,+ ilẹ̀ yóò mú èso jáde,+ àwọn igi oko yóò sì so èso. Sáàmù 67:6 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 6 Ilẹ̀ yóò mú èso jáde;+Ọlọ́run, àní Ọlọ́run wa, yóò bù kún wa.+ Àìsáyà 25:6 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 6 Lórí òkè yìí,+ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa se àkànṣe àsè tó dọ́ṣọ̀+Fún gbogbo èèyàn,Àkànṣe àsè tó ní wáìnì tó dáa,*Àsè tó dọ́ṣọ̀ tí mùdùnmúdùn kún inú rẹ̀,Àsè tó ní wáìnì tó dáa tí wọ́n sẹ́. Àìsáyà 30:23 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 23 Ó máa rọ òjò sí ohun tí o gbìn sínú ilẹ̀,+ oúnjẹ tí ilẹ̀ bá sì mú jáde máa pọ̀ rẹpẹtẹ, ó sì máa lọ́ràá.*+ Ní ọjọ́ yẹn, ẹran ọ̀sìn rẹ máa jẹko ní àwọn pápá tó fẹ̀.+
6 Lórí òkè yìí,+ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa se àkànṣe àsè tó dọ́ṣọ̀+Fún gbogbo èèyàn,Àkànṣe àsè tó ní wáìnì tó dáa,*Àsè tó dọ́ṣọ̀ tí mùdùnmúdùn kún inú rẹ̀,Àsè tó ní wáìnì tó dáa tí wọ́n sẹ́.
23 Ó máa rọ òjò sí ohun tí o gbìn sínú ilẹ̀,+ oúnjẹ tí ilẹ̀ bá sì mú jáde máa pọ̀ rẹpẹtẹ, ó sì máa lọ́ràá.*+ Ní ọjọ́ yẹn, ẹran ọ̀sìn rẹ máa jẹko ní àwọn pápá tó fẹ̀.+