Sáàmù 40:5 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 5 Wo bí àwọn ohun tí o ṣe ti pọ̀ tó,Jèhófà Ọlọ́run mi,Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ àti èrò rẹ sí wa.+ Kò sí ẹni tí a lè fi ọ́ wé;+Tí mo bá ní kí n máa wí, kí n sì máa sọ nípa wọn,Wọ́n pọ̀ ju ohun tí mo lè ròyìn!+ Sáàmù 145:4 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 4 Ìran dé ìran yóò máa yin àwọn iṣẹ́ rẹ;Wọ́n á máa sọ nípa iṣẹ́ ńlá rẹ.+ Oníwàásù 3:11 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 11 Ó ti ṣe ohun gbogbo rèǹtèrente* ní ìgbà tirẹ̀.+ Kódà ó ti fi ayérayé sí wọn lọ́kàn; síbẹ̀ aráyé ò lè rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Ìfihàn 15:3 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 3 Wọ́n ń kọ orin Mósè+ ẹrú Ọlọ́run àti orin Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ náà, pé: “Jèhófà* Ọlọ́run, Olódùmarè,+ àwọn iṣẹ́ rẹ tóbi, ó sì kàmàmà.+ Òdodo àti òótọ́ ni àwọn ọ̀nà rẹ,+ Ọba ayérayé.+
5 Wo bí àwọn ohun tí o ṣe ti pọ̀ tó,Jèhófà Ọlọ́run mi,Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ àti èrò rẹ sí wa.+ Kò sí ẹni tí a lè fi ọ́ wé;+Tí mo bá ní kí n máa wí, kí n sì máa sọ nípa wọn,Wọ́n pọ̀ ju ohun tí mo lè ròyìn!+
11 Ó ti ṣe ohun gbogbo rèǹtèrente* ní ìgbà tirẹ̀.+ Kódà ó ti fi ayérayé sí wọn lọ́kàn; síbẹ̀ aráyé ò lè rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.
3 Wọ́n ń kọ orin Mósè+ ẹrú Ọlọ́run àti orin Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ náà, pé: “Jèhófà* Ọlọ́run, Olódùmarè,+ àwọn iṣẹ́ rẹ tóbi, ó sì kàmàmà.+ Òdodo àti òótọ́ ni àwọn ọ̀nà rẹ,+ Ọba ayérayé.+