-
Hébérù 3:7-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Torí náà, bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe sọ pé,+ “Lónìí, tí ẹ bá fetí sí ohùn rẹ̀, 8 ẹ má ṣe mú kí ọkàn yín le bó ṣe rí nígbà tí ẹ fa ìbínú tó le gan-an, bíi ti ọjọ́ tí ẹ fa àdánwò ní aginjù,+ 9 níbi tí àwọn baba ńlá yín ti dán mi wò, tí wọ́n sì dẹ mí wò, láìka àwọn iṣẹ́ mi tí wọ́n rí fún ogójì (40) ọdún sí.+ 10 Ìdí nìyẹn tí ọ̀rọ̀ ìran yìí fi kó mi nírìíra, tí mo sì sọ pé: ‘Àwọn èèyàn tó máa ń ṣìnà nínú ọkàn ni wọ́n, wọn ò sì tíì mọ àwọn ọ̀nà mi.’ 11 Torí náà, mo búra nínú ìbínú mi pé, ‘Wọn ò ní wọnú ìsinmi mi.’”+
-