-
Sáàmù 95:7-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
Lónìí, tí ẹ bá fetí sí ohùn rẹ̀,+
8 Ẹ má ṣe mú kí ọkàn yín le bí ẹ ṣe ṣe ní Mẹ́ríbà,*+
9 Nígbà tí àwọn baba ńlá yín dán mi wò;+
Wọ́n pè mí níjà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti rí àwọn iṣẹ́ mi.+
10 Ogójì (40) ọdún ni mo fi kórìíra ìran yẹn, mo sì sọ pé:
“Àwọn èèyàn tó máa ń ṣìnà nínú ọkàn wọn ni wọ́n;
Wọn ò tíì mọ àwọn ọ̀nà mi.”
11 Torí náà, mo búra nínú ìbínú mi pé:
“Wọn ò ní wọnú ìsinmi mi.”+
-