-
Nọ́ńbà 26:63, 64Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
63 Èyí ni àwọn tí Mósè àti àlùfáà Élíásárì forúkọ wọn sílẹ̀ nígbà tí wọ́n forúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Móábù, nítòsí Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò. 64 Àmọ́ ìkankan nínú wọn kò sí lára àwọn tí Mósè àti àlùfáà Áárónì forúkọ wọn sílẹ̀ nígbà tí wọ́n ka iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní aginjù Sínáì.+
-
-
Diutarónómì 1:35Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
35 ‘Ìkankan nínú àwọn èèyàn yìí tí wọ́n wà lára ìran búburú yìí kò ní rí ilẹ̀ dáradára tí mo búra pé màá fún àwọn bàbá yín,+
-
-
Sáàmù 95:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Torí náà, mo búra nínú ìbínú mi pé:
“Wọn ò ní wọnú ìsinmi mi.”+
-
-
Sáàmù 106:26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Torí náà, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè láti búra nípa wọn
Pé òun máa mú kí wọ́n ṣubú ní aginjù;+
-
Hébérù 3:18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Àwọn wo ló sì búra fún pé wọn ò ní wọnú ìsinmi òun? Ṣebí àwọn tó ṣàìgbọràn ni?
-
-
-