28 Sọ fún wọn pé, ‘“Ó dájú pé bí mo ti wà láàyè,” ni Jèhófà wí, “ohun tí mo gbọ́ tí ẹ sọ+ gẹ́lẹ́ ni màá ṣe sí yín! 29 Inú aginjù yìí lẹ máa kú sí,+ àní gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè nínú yín, àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kùn sí mi.+