2 Ìgbà náà ni Ọba Dáfídì dìde dúró, ó sì sọ pé:
“Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin arákùnrin mi àti ẹ̀yin èèyàn mi. Ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn mi láti kọ́ ilé tó máa jẹ́ ibi ìsinmi fún àpótí májẹ̀mú Jèhófà, tí á sì jẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ fún Ọlọ́run wa,+ mo sì ti ṣètò sílẹ̀ láti kọ́ ọ.+