-
Dáníẹ́lì 9:20, 21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, tí mò ń gbàdúrà, tí mò ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi àti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì, tí mo sì ń bẹ̀bẹ̀ fún ojúure Jèhófà Ọlọ́run mi nítorí òkè mímọ́ Ọlọ́run mi,+ 21 àní, bí mo ṣe ń gbàdúrà lọ́wọ́, ọkùnrin náà Gébúrẹ́lì,+ ẹni tí mo ti rí nínú ìran tẹ́lẹ̀,+ wá sọ́dọ̀ mi nígbà tí okun ti tán nínú mi pátápátá, nígbà tí àkókò ọrẹ alẹ́ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó.
-