-
Ìṣe 13:34-37Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
34 Bí Ó ṣe jí i dìde nínú ikú, tí kò sì jẹ́ kó pa dà sí ara tó lè díbàjẹ́ mọ́, ó sọ ọ́ lọ́nà yìí pé: ‘Màá fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí mo ṣèlérí fún Dáfídì hàn sí ọ, èyí tó jẹ́ òtítọ́.’*+ 35 Bákan náà, ó tún wà nínú sáàmù míì pé: ‘O ò ní jẹ́ kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ rí ìdíbàjẹ́.’+ 36 Dáfídì ní tirẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn fún* Ọlọ́run ní ìran rẹ̀, ó sùn nínú ikú, wọ́n sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, ó sì rí ìdíbàjẹ́.+ 37 Àmọ́, ẹni tí Ọlọ́run gbé dìde kò rí ìdíbàjẹ́.+
-