-
Léfítíkù 16:21, 22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Kí Áárónì gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé orí ààyè ewúrẹ́ náà, kó jẹ́wọ́ gbogbo àṣìṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti gbogbo ìṣìnà wọn àti gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn sórí rẹ̀, kí ó kó o lé orí ewúrẹ́+ náà, kó wá yan ẹnì kan* tó máa rán ewúrẹ́ náà lọ sínú aginjù. 22 Kí ewúrẹ́ náà fi orí rẹ̀ ru gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn+ lọ sí aṣálẹ̀,+ kó sì rán ewúrẹ́ náà lọ sínú aginjù.+
-