19 Mikáyà bá sọ pé: “Nítorí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà: Mo rí Jèhófà tó jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀,+ gbogbo ọmọ ogun ọ̀run sì dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, lápá ọ̀tún àti lápá òsì.+
13 Lójijì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun ọ̀run+ wá bá áńgẹ́lì náà, wọ́n ń yin Ọlọ́run, wọ́n sì ń sọ pé: 14 “Ògo ni fún Ọlọ́run ní ibi gíga lókè àti àlàáfíà fún àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà* ní ayé.”