-
Ìsíkíẹ́lì 1:27, 28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Mo sì rí ohun kan tó ń dán yanran bí àyọ́pọ̀ wúrà àti fàdákà,+ ó rí bí iná, ó jọ pé ó ń jó látibi ìbàdí rẹ̀ lọ sókè; mo rí ohun kan tó dà bí iná+ láti ìbàdí rẹ̀ lọ sísàlẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ sì tàn yòò yí i ká 28 bí òṣùmàrè+ tó yọ lójú ọ̀run lọ́jọ́ tí òjò rọ̀. Bí ìmọ́lẹ̀ iná tó yí i ká ṣe rí nìyẹn. Ó rí bí ògo Jèhófà.+ Nígbà tí mo rí i, mo dojú bolẹ̀, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ohùn ẹnì kan tó ń sọ̀rọ̀.
-