Sáàmù 136:25 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 25 Ó ń fún gbogbo ohun alààyè* ní oúnjẹ,+Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé. Sáàmù 145:15 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 15 Ojú rẹ ni gbogbo ẹ̀dá ń wò,Ò ń fún wọn ní oúnjẹ wọn lásìkò.+ Sáàmù 147:9 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 9 Ó ń fún àwọn ẹranko lóúnjẹ,+Àwọn ọmọ ẹyẹ ìwò tó ń kígbe fún oúnjẹ.+ Mátíù 6:26 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 26 Ẹ fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run;+ wọn kì í fúnrúgbìn tàbí kárúgbìn tàbí kí wọ́n kó nǹkan jọ sínú ilé ìkẹ́rùsí, síbẹ̀ Baba yín ọ̀run ń bọ́ wọn. Ṣé ẹ ò wá níye lórí jù wọ́n lọ ni?
26 Ẹ fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run;+ wọn kì í fúnrúgbìn tàbí kárúgbìn tàbí kí wọ́n kó nǹkan jọ sínú ilé ìkẹ́rùsí, síbẹ̀ Baba yín ọ̀run ń bọ́ wọn. Ṣé ẹ ò wá níye lórí jù wọ́n lọ ni?