8 “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà,+ ẹ ké pe orúkọ rẹ̀,
Ẹ jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ àwọn ohun tí ó ṣe!+
9 Ẹ kọrin sí i, ẹ fi orin yìn ín,+
Ẹ máa ronú lórí gbogbo àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀.+
10 Ẹ máa fi orúkọ mímọ́+ rẹ̀ yangàn.
Kí ọkàn àwọn tó ń wá Jèhófà máa yọ̀.+
11 Ẹ máa wá Jèhófà+ àti agbára rẹ̀.
Ẹ máa wá ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.+
12 Ẹ máa rántí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu tó ti ṣe,+
Àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àti àwọn ìdájọ́ tó kéde,
13 Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì ìránṣẹ́ rẹ̀,+
Ẹ̀yin ọmọ Jékọ́bù, ẹ̀yin àyànfẹ́ rẹ̀.+