105 Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà,+ ẹ ké pe orúkọ rẹ̀,
Ẹ jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ àwọn ohun tí ó ṣe!+
2 Ẹ kọrin sí i, ẹ fi orin yìn ín,
Ẹ máa ronú lórí gbogbo àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀.+
3 Ẹ máa fi orúkọ mímọ́ rẹ̀ yangàn.+
Kí ọkàn àwọn tó ń wá Jèhófà máa yọ̀.+
4 Ẹ máa wá Jèhófà+ àti agbára rẹ̀.
Ẹ máa wá ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.
5 Ẹ máa rántí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu tó ti ṣe,
Àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àti àwọn ìdájọ́ tó kéde,+
6 Ẹ̀yin ọmọ Ábúráhámù ìránṣẹ́ rẹ̀,+
Ẹ̀yin ọmọ Jékọ́bù, ẹ̀yin àyànfẹ́ rẹ̀.+