15 Ẹ máa rántí májẹ̀mú rẹ̀ títí láé,
Ẹ máa rántí ìlérí tó ṣe títí dé ẹgbẹ̀rún ìran,+
16 Májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù dá+
Àti ìbúra rẹ̀ fún Ísákì,+
17 Èyí tó gbé kalẹ̀ bí ìlànà fún Jékọ́bù+
Àti bíi májẹ̀mú tó wà títí láé fún Ísírẹ́lì,
18 Ó ní, ‘Màá fún ọ ní ilẹ̀ Kénáánì+
Bí ogún tí a pín fún yín.’+