ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 12:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Jèhófà wá fara han Ábúrámù, ó sì sọ pé: “Ọmọ* rẹ+ ni èmi yóò fún ní ilẹ̀ yìí.”+ Ó sì mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Jèhófà, ẹni tó fara hàn án.

  • Jẹ́nẹ́sísì 13:14, 15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Jèhófà sọ fún Ábúrámù lẹ́yìn tí Lọ́ọ̀tì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ pé: “Jọ̀ọ́ gbójú sókè níbi tí o wà, kí o sì wo àríwá àti gúúsù, ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn, 15 torí gbogbo ilẹ̀ tí o rí yìí ni màá fún ìwọ àti ọmọ* rẹ, yóò sì di ohun ìní yín títí láé.+

  • Jẹ́nẹ́sísì 15:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà bá Ábúrámù dá májẹ̀mú+ kan pé: “Ọmọ* rẹ ni èmi yóò fún ní ilẹ̀ yìí,+ láti odò Íjíbítì dé odò ńlá náà, ìyẹn odò Yúfírétì:+

  • Jẹ́nẹ́sísì 26:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Máa gbé ilẹ̀+ yìí bí àjèjì, màá wà pẹ̀lú rẹ, màá sì bù kún ọ torí pé ìwọ àti ọmọ* rẹ ni màá fún ní gbogbo ilẹ̀+ yìí, màá sì ṣe ohun tí mo búra fún Ábúráhámù+ bàbá rẹ pé:

  • Jẹ́nẹ́sísì 28:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Wò ó! Jèhófà wà lókè rẹ̀, ó sì sọ pé:

      “Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run Ábúráhámù bàbá rẹ àti Ọlọ́run Ísákì.+ Ìwọ àti àtọmọdọ́mọ*+ rẹ ni màá fún ní ilẹ̀ tí o dùbúlẹ̀ sí yìí.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́