Sáàmù 18:36 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 36 O fẹ ọ̀nà fún ẹsẹ̀ mi;Kí ẹsẹ̀* mi má bàa yọ̀.+ Sáàmù 94:18 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 18 Nígbà tí mo sọ pé: “Ẹsẹ̀ mi ń yọ̀,”Jèhófà, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ló ń gbé mi ró.+ Sáàmù 119:133 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 133 Fi ọ̀rọ̀ rẹ darí ìṣísẹ̀ mi láìséwu;*Kí aburú kankan má ṣe jọba lórí mi.+ Sáàmù 121:3 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 3 Kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ yọ̀.*+ Ẹni tó ń ṣọ́ ọ kò ní tòògbé láé.