-
Jẹ́nẹ́sísì 23:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 “Àjèjì ni mo jẹ́ nílẹ̀ yìí,+ àárín yín ni mo sì ń gbé. Ẹ fún mi níbì kan tí mo lè sìnkú sí nílẹ̀ yín, kí n lè sin òkú ìyàwó mi síbẹ̀.”
-
-
Ìṣe 7:4, 5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Lẹ́yìn náà, ó jáde kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà, ó sì ń gbé ní Háránì. Lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀ kú,+ Ọlọ́run darí rẹ̀ láti ibẹ̀ pé kí ó lọ máa gbé ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gbé báyìí.+ 5 Síbẹ̀, kò fún un ní ogún kankan nínú rẹ̀, rárá, kò tiẹ̀ fún un ní ibi tó lè gbẹ́sẹ̀ lé; àmọ́ ó ṣèlérí pé òun máa fún un láti fi ṣe ohun ìní, lẹ́yìn rẹ̀ òun á fún ọmọ* rẹ̀,+ bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò tíì ní ọmọ kankan.
-