2 Ábúráhámù tún sọ nípa Sérà ìyàwó rẹ̀ pé: “Àbúrò mi ni.”+ Ni Ábímélékì ọba Gérárì bá ránṣẹ́ pe Sérà, ó sì mú un sọ́dọ̀.+ 3 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run bá Ábímélékì sọ̀rọ̀ lójú àlá ní òru, ó sọ fún un pé: “Wò ó, o ti kú tán torí obìnrin tí o mú yìí,+ ó ti lọ́kọ, ìyàwó oníyàwó+ sì ni.”