4 Jósẹ́fù sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ sún mọ́ mi.” Ni wọ́n bá sún mọ́ ọn.
Ó sọ pé: “Èmi ni Jósẹ́fù arákùnrin yín, tí ẹ tà sí Íjíbítì.+ 5 Àmọ́ ẹ má banú jẹ́, ẹ má sì bínú sí ara yín torí pé ẹ tà mí síbí; torí Ọlọ́run ti rán mi ṣáájú yín láti gba ẹ̀mí là.+