-
Jẹ́nẹ́sísì 41:39-41Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
39 Ni Fáráò bá sọ fún Jósẹ́fù pé: “Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ló jẹ́ kí o mọ gbogbo èyí, kò sí ẹni tó lóye, tó sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n bíi tìẹ. 40 Ìwọ ni màá fi ṣe olórí ilé mi, gbogbo àwọn èèyàn mi yóò sì máa ṣègbọràn sí ọ délẹ̀délẹ̀.+ Ipò ọba* mi nìkan ni màá fi jù ọ́ lọ.” 41 Fáráò tún sọ fún Jósẹ́fù pé: “Wò ó, èmi yóò fi ọ́ ṣe olórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.”+
-
-
Jẹ́nẹ́sísì 41:48Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
48 Ó sì ń kó gbogbo oúnjẹ jọ ní ilẹ̀ Íjíbítì fún ọdún méje náà, ó ń kó oúnjẹ pa mọ́ sí àwọn ìlú. Ó máa ń kó àwọn irè oko agbègbè ìlú kọ̀ọ̀kan pa mọ́ sí ìlú náà.
-