-
Ẹ́kísódù 7:20, 21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Lójú ẹsẹ̀, Mósè àti Áárónì ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ gẹ́lẹ́. Ó na ọ̀pá náà sókè, ó sì fi lu omi odò Náílì níṣojú Fáráò àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, gbogbo omi odò náà sì di ẹ̀jẹ̀.+ 21 Àwọn ẹja inú odò náà kú,+ odò náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í rùn, àwọn ará Íjíbítì kò wá lè mu omi odò Náílì,+ ẹ̀jẹ̀ sì wà ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.
-