-
Ẹ́kísódù 10:13-15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Ni Mósè bá na ọ̀pá rẹ̀ sórí ilẹ̀ Íjíbítì, Jèhófà sì mú kí atẹ́gùn fẹ́ wá láti ìlà oòrùn sí ilẹ̀ náà lọ́jọ́ yẹn tọ̀sántòru. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, atẹ́gùn tó fẹ́ wá láti ìlà oòrùn gbé àwọn eéṣú wá. 14 Àwọn eéṣú náà kún gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì, wọ́n sì bo gbogbo agbègbè Íjíbítì.+ Wọ́n ṣọṣẹ́ gan-an;+ eéṣú ò tíì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ rí, wọn ò sì ní pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ mọ́ láé. 15 Wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ náà, wọ́n sì mú kí ilẹ̀ náà ṣókùnkùn. Wọ́n jẹ gbogbo ewéko ilẹ̀ náà run àti gbogbo èso igi tí òjò yìnyín ṣẹ́ kù; kò sí ewé kankan lórí àwọn igi tàbí ohun ọ̀gbìn ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.
-