-
Ẹ́kísódù 14:19, 20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Áńgẹ́lì Ọlọ́run tòótọ́+ tó ń lọ níwájú àwùjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò níwájú, ó sì bọ́ sí ẹ̀yìn wọn, ọwọ̀n ìkùukùu* tó wà níwájú wọn wá bọ́ sí ẹ̀yìn wọn, ó sì dúró síbẹ̀.+ 20 Ó wà láàárín àwùjọ àwọn ará Íjíbítì àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ Ó mú kí òkùnkùn ṣú lápá kan. Àmọ́ lápá kejì, ó mú kí ìmọ́lẹ̀ wà ní òru yẹn.+ Torí náà, àwùjọ kìíní ò dé ọ̀dọ̀ àwùjọ kejì ní gbogbo òru yẹn.
-