-
Ẹ́kísódù 16:12-15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 “Mo ti gbọ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń kùn.+ Sọ fún wọn pé, ‘Ní ìrọ̀lẹ́,* ẹ ó jẹ ẹran, tó bá sì di àárọ̀, ẹ ó jẹ oúnjẹ ní àjẹyó,+ ó sì dájú pé ẹ ó mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’”+
13 Torí náà, ní alẹ́ ọjọ́ yẹn, àwọn àparò fò wá, wọ́n sì bo ibi tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pàgọ́ sí,+ nígbà tó sì di àárọ̀, ìrì ti sẹ̀ yí ká ibi tí wọ́n pàgọ́ sí. 14 Nígbà tí ìrì náà gbẹ, ohun kan wà lórí ilẹ̀ ní aginjù náà tó rí wínníwínní.+ Ó rí bíi yìnyín tó rọ̀ sórí ilẹ̀. 15 Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí i, wọ́n ń bi ara wọn pé, “Kí nìyí?” torí wọn ò mọ ohun tó jẹ́. Mósè sọ fún wọn pé: “Oúnjẹ tí Jèhófà fún yín pé kí ẹ jẹ ni.+
-